11 Apoti-ẹri Oluwa si gbe ni ile Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: Oluwa si bukún fun Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rẹ̀.
12 A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀.
13 O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ.
14 Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀.
15 Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè.
16 Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.
17 Nwọn si mu apoti-ẹri Oluwa na wá, nwọn si gbe e kalẹ sipò rẹ̀ larin agọ na ti Dafidi pa fun u: Dafidi si rubọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa.