14 Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀.
15 Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè.
16 Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.
17 Nwọn si mu apoti-ẹri Oluwa na wá, nwọn si gbe e kalẹ sipò rẹ̀ larin agọ na ti Dafidi pa fun u: Dafidi si rubọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa.
18 Dafidi si pari iṣẹ ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na, o si sure fun awọn enia na li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun.
19 O si pin fun gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo ọpọ enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin; fun olukuluku iṣu akara kan ati ẹkirí ẹran kan, ati akara didun kan. Gbogbo awọn enia na si tuka lọ, olukuluku si ile rẹ̀.
20 Dafidi si yipada lati sure fun awọn ara ile rẹ̀, Mikali ọmọbinrin Saulu si jade lati wá pade Dafidi, o si wipe, Bi o ti ṣe ohun ogo to loni fun ọba Israeli, ti o bọ ara rẹ̀ silẹ loni loju awọn iranṣẹbinrin awọn iranṣẹ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn enia asan iti bọra rẹ̀ silẹ!