20 Dafidi si yipada lati sure fun awọn ara ile rẹ̀, Mikali ọmọbinrin Saulu si jade lati wá pade Dafidi, o si wipe, Bi o ti ṣe ohun ogo to loni fun ọba Israeli, ti o bọ ara rẹ̀ silẹ loni loju awọn iranṣẹbinrin awọn iranṣẹ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn enia asan iti bọra rẹ̀ silẹ!
21 Dafidi si wi fun Mikali pe, Niwaju Oluwa ni, ẹniti o yàn mi fẹ jù baba rẹ lọ, ati ju gbogbo idile rẹ̀ lọ, lati fi emi ṣe olori awọn enia Oluwa, ani lori Israeli, emi o si ṣire niwaju Oluwa.
22 Emi o si tun rẹ̀ ara mi silẹ jù bẹ̃ lọ, emi o si ṣe alainiyìn loju ara mi, ati loju awọn iranṣẹbinrin wọnni ti iwọ wi, lọdọ wọn na li emi o si li ogo.
23 Mikali ọmọbinrin Saulu kò si bi ọmọ, titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀.