24 Iwọ si fi idi awọn enia rẹ, ani Israeli, kalẹ fun ara rẹ lati sọ wọn di enia rẹ titi lai: iwọ Oluwa si wa di Ọlọrun fun wọn.
25 Njẹ, Oluwa Ọlọrun, jẹ ki ọ̀rọ na ti iwọ sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti idile rẹ̀, ki o duro titi lai, ki o si ṣe bi iwọ ti wi.
26 Jẹ ki orukọ rẹ ki o ga titi lai, pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li Ọlọrun lori Israeli: si jẹ ki a fi idile Dafidi iranṣẹ rẹ mulẹ niwaju rẹ.
27 Nitoripe iwọ, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli ti sọ li eti iranṣẹ rẹ, pe, emi o ṣe idile kan fun ọ: nitorina ni iranṣẹ rẹ si ṣe ni i li ọkàn rẹ̀ lati gbadura yi si ọ.
28 Njẹ, Oluwa Ọlọrun, iwọ li Ọlọrun na, ọrọ rẹ wọnni yio si jasi otitọ, iwọ si jẹ'jẹ nkan rere yi fun iranṣẹ rẹ:
29 Njẹ, jẹ ki o wù ọ lati bukún idile iranṣẹ rẹ, ki o wà titi lai niwaju rẹ: nitori iwọ, Oluwa Ọlọrun, li o ti sọ ọ: si jẹ ki ibukún ki o wà ni idile iranṣẹ rẹ titi lai, nipasẹ ibukún rẹ.