16 Awọn orilẹ-ède yio ri, oju o si tì wọn ninu gbogbo agbara wọn: nwọn o fi ọwọ́ le ẹnu, eti wọn o si di.
17 Nwọn o lá erùpẹ bi ejò, nwọn o si jade kuro ninu ihò wọn bi ekòlo ilẹ: nwọn o bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa, nwọn o si bẹ̀ru nitori rẹ.
18 Tani Ọlọrun bi iwọ, ti o ndari aiṣedede jì, ti o nre iyokù ini rẹ̀ kọja? kò dá ibinu rẹ̀ duro titi lai, nitori on ni inudidun si ãnu.
19 Yio yipadà, yio ni iyọnú si wa; yio si tẹ̀ aiṣedede wa ba; iwọ o si sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn sinu ọgbun okun.
20 Iwọ o fi otitọ fun Jakobu, ãnu fun Abrahamu, ti iwọ ti bura fun awọn baba wa, lati ọjọ igbani.