4 O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ.
5 Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6 Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata.
7 Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e.
8 Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀.
9 Kili ẹnyin ngbirò si Oluwa? on o ṣe iparun de opin, ipọnju kì yio dide lẹrinkeji.
10 Nitori sã ti a ba ká wọn jọ bi ẹ̀gun, ati sã ti wọn iba mu amupara bi ọmùti, a o run wọn gẹgẹ bi koriko ti o ti gbẹ de opin.