3 Ẹlẹṣin ti gbe idà rẹ̀ ti nkọ màna, ati ọkọ̀ rẹ̀ ti ndán yànran si oke: ọ̀pọlọpọ si li awọn ẹniti a pa, ati ọ̀pọlọpọ okú; okú kò si ni opin; nwọn nkọsẹ̀ li ara okú wọn wọnni:
4 Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀.
5 Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba.
6 Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà.
7 Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ?
8 Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá?
9 Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ.