11 Nitõtọ bi ejo ba bu ni ṣán lainitùju; njẹ ère kì yio si fun onitùju.
12 Ọ̀rọ ẹnu ọlọgbọ̀n li ore-ọfẹ; ṣugbọn ète aṣiwère ni yio gbe ara rẹ̀ mì.
13 Ipilẹṣẹ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni wère: ati opin ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni isinwin iparun.
14 Aṣiwère pẹlu kún fun ọ̀rọ pupọ: enia kò le sọ ohun ti yio ṣẹ; ati ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀, tali o le wi fun u?
15 Lãla aṣiwère da olukuluku wọn li agara, nitoriti kò mọ̀ bi a ti lọ si ilu.
16 Egbé ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba ṣe ọmọde, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun ni kutukutu.
17 Ibukún ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba jẹ ọmọ ọlọlá, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun li akoko ti o yẹ, fun ilera ti kì si iṣe fun ọti amupara!