Oni 10 YCE

1 OKÚ eṣinṣin o mu ororo-ikunra alapolu bajẹ ki o ma run õrùn buburu: bẹ̃ni wère diẹ wuwo jù ọgbọ́n ati ọlá lọ.

2 Aiya ọlọgbọ́n mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ṣugbọn aiya aṣiwère li ọwọ òsi rẹ̀.

3 Ati pẹlu nigbati ẹniti o ṣiwère ba nrìn li ọ̀na, ọgbọ́n rẹ̀ a fò lọ, on a si wi fun olukuluku enia pe aṣiwère li on.

4 Bi ọkàn ijoye ba ru si ọ, máṣe fi ipò rẹ silẹ; nitoripe itũbá ama tù ẹ̀ṣẹ nla.

5 Buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, bi ìṣina ti o ti ọdọ awọn ijoye wá.

6 A gbe aṣiwère sipò ọlá, awọn ọlọrọ̀ si joko nipò ẹhin.

7 Mo ri awọn ọmọ-ọdọ lori ẹṣin, ati awọn ọmọ-alade nrìn bi ọmọ-ọdọ ni ilẹ.

8 Ẹniti o wà iho ni yio bọ́ sinu rẹ̀; ati ẹniti o si njá ọgbà tútù, ejo yio si bù u ṣán.

9 Ẹnikan ti o nyi okuta ni yio si ti ipa rẹ̀ ni ipalara; ati ẹniti o si nla igi ni yio si wu li ewu.

10 Bi irin ba kújú, ti on kò si pọn oju rẹ̀, njẹ ki on ki o fi agbara si i; ṣugbọn ère ọgbọ́n ni lati fi ọ̀na hàn.

11 Nitõtọ bi ejo ba bu ni ṣán lainitùju; njẹ ère kì yio si fun onitùju.

12 Ọ̀rọ ẹnu ọlọgbọ̀n li ore-ọfẹ; ṣugbọn ète aṣiwère ni yio gbe ara rẹ̀ mì.

13 Ipilẹṣẹ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni wère: ati opin ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni isinwin iparun.

14 Aṣiwère pẹlu kún fun ọ̀rọ pupọ: enia kò le sọ ohun ti yio ṣẹ; ati ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀, tali o le wi fun u?

15 Lãla aṣiwère da olukuluku wọn li agara, nitoriti kò mọ̀ bi a ti lọ si ilu.

16 Egbé ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba ṣe ọmọde, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun ni kutukutu.

17 Ibukún ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba jẹ ọmọ ọlọlá, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun li akoko ti o yẹ, fun ilera ti kì si iṣe fun ọti amupara!

18 Nipa ilọra pupọ igi ile a hù; ati nipa ọlẹ ọwọ, ile a si ma jò.

19 Ẹrín li a nsàse fun, ati ọti-waini ni imu inu alãye dùn: owo si ni idahùn ohun gbogbo.

20 Máṣe bu ọba, ki o má ṣe ninu èro rẹ; máṣe bu ọlọrọ̀ ni iyẹwu rẹ; nitoripe ẹiyẹ oju-ọrun yio gbe ohùn na lọ, ohun ti o ni iyẹ-apá yio si sọ ọ̀ran na.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12