1 Ọ̀RỌ oniwasu, ọmọ Dafidi, ti o jọba ni Jerusalemu.
2 Asan inu asan, oniwasu na wipe, asan inu asan; gbogbo rẹ̀ asan ni!
3 Ere kili enia jẹ ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn?
4 Iran kan lọ, iran miran si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai.
5 Õrun pẹlu là, õrun si wọ̀, o si yara lọ si ipò rẹ̀ nibiti o ti là.
6 Afẹfẹ nfẹ lọ siha gusu, a si yipada siha ariwa; o si nlọ sihin sọhun titi, afẹfẹ si tun pada gẹgẹ nipa ayika rẹ̀.
7 Odò gbogbo ni nṣan sinu okun; ṣugbọn okun kò kún, nibiti awọn odò ti nṣàn wá, nibẹ ni nwọn si tun pada lọ.
8 Ọ̀rọ gbogbo kò to; enia kò le sọ ọ: iran kì isu oju, bẹ̃li eti kì ikún fun gbigbọ́.
9 Ohun ti o wà, on ni yio si wà; ati eyiti a ti ṣe li eyi ti a o ṣe; kò si ohun titun labẹ õrùn.
10 Ohun kan wà nipa eyi ti a wipe, Wò o, titun li eyi! o ti wà na nigba atijọ, ti o ti wà ṣaju wa.
11 Kò si iranti ohun iṣaju; bẹ̃ni iranti kì yio si fun ohun ikẹhin ti mbọ̀, lọdọ awọn ti mbọ̀ ni igba ikẹhin.
12 Emi oniwasu jọba lori Israeli ni Jerusalemu.
13 Mo si fi aiya mi si ati ṣe afẹri on ati wadi ọgbọ́n niti ohun gbogbo ti a nṣe labẹ ọrun, lãla kikan yi li Ọlorun fi fun awọn ọmọ enia lati ṣe lãla ninu rẹ̀.
14 Mo ti ri iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo.
15 Eyi ti o wọ́, a kò le mu u tọ́: ati iye àbuku, a kò le kà a.
16 Mo si ba aiya ara mi sọ̀rọ wipe, kiyesi i, mo li ọgbọ́n nla, mo si fi kún u jù gbogbo wọn lọ ti o ti ṣaju mi ni Jerusalemu; aiya mi si ri ohun pupọ nla niti ọgbọ́n ati ti ìmọ.
17 Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, ati lati mọ̀ isinwin ati iwère: nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi pẹlu jẹ imulẹmofo.
18 Nitoripe ninu ọgbọ́n pupọ ni ibinujẹ pupọ wà, ẹniti o si nsọ ìmọ di pupọ, o nsọ ikãnu di pupọ.