Oni 5 YCE

1 PA ẹsẹ rẹ mọ́ nigbati iwọ ba nlọ si ile Ọlọrun, ki iwọ ki o si mura ati gbọ́ jù ati ṣe irubọ aṣiwère: nitoriti nwọn kò rò pe nwọn nṣe ibi.

2 Máṣe fi ẹnu rẹ yara, ki o má si jẹ ki aiya rẹ ki o yara sọ ọ̀rọ niwaju Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun mbẹ li ọrun, iwọ si mbẹ li aiye: nitorina jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o mọ̀ ni ìwọn.

3 Nitoripe nipa ọ̀pọlọpọ iṣẹ ni alá ti iwá; bẹ̃ni nipa ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ li ã mọ̀ ohùn aṣiwère.

4 Nigbati iwọ ba jẹ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a: nitori kò ni inu-didun si aṣiwère: san eyi ti iwọ jẹjẹ́.

5 O san ki iwọ ki o má jẹ ẹjẹ́, jù ki iwọ ki o jẹ ẹjẹ́, ki o má san a.

6 Máṣe jẹ ki ẹnu rẹ ki o mu ara rẹ ṣẹ̀: ki iwọ ki o má si ṣe wi niwaju iranṣẹ Ọlọrun pe, èṣi li o ṣe: nitori kili Ọlọrun yio ṣe binu si ohùn rẹ, a si ba iṣẹ ọwọ rẹ jẹ?

7 Nitoripe bi ninu ọ̀pọlọpọ alá ni asan wà, bẹ̃ni ninu ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ pẹlu: ṣugbọn iwọ bẹ̀ru Ọlọrun.

8 Bi iwọ ba ri inilara awọn olupọnju, ati ifi agbara yi idajọ ati otitọ pada ni igberiko, máṣe jẹ ki ẹnu ki o yà ọ si ọ̀ran na: nitoripe ẹniti o ga jù nṣọ ẹniti o ga, ati ẹni-giga-julọ wà lori wọn.

9 Pẹlupẹlu ère ilẹ ni fun gbogbo enia: a si nsìn ọba tikalarẹ pãpa lati inu oko wa.

10 Ẹniti o ba fẹ fadaka, fadaka kì yio tẹ́ ẹ lọrun; bẹ̃li ẹniti o fẹ ọrọ̀ kì yio tẹ́ ẹ lọrun: asan li eyi pẹlu.

11 Nigbati ẹrù ba npọ̀ si i, awọn ti o si njẹ ẹ a ma pọ̀ si i: ore ki tilẹ ni fun ẹniti o ni i bikoṣepe ki nwọn ki o ma fi oju wọn wò o?

12 Didùn ni orun oniṣẹ, iba jẹ onjẹ diẹ tabi pupọ: ṣugbọn itẹlọrun ọlọrọ̀ kì ijẹ, ki o sùn.

13 Ibi buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, eyini ni pe, ọrọ̀ ti a pamọ́ fun ifarapa awọn ti o ni i.

14 Nitori ọrọ̀ wọnni a ṣegbe nipa iṣẹ buburu; bi o si bi ọmọkunrin kan, kò ni nkan lọwọ rẹ̀.

15 Bi o ti ti inu iya rẹ̀ jade wá, ihoho ni yio si tun pada lọ bi o ti wá, kì yio si mu nkan ninu lãla rẹ̀, ti iba mu lọ lọwọ rẹ̀.

16 Ibi buburu li eyi pẹlu, pe li ọ̀na gbogbo, bi o ti wá, bẹ̃ni yio si lọ: ère ki si ni fun ẹniti nṣe lãla fun afẹfẹ?

17 Li ọjọ rẹ̀ gbogbo pẹlu, o njẹun li òkunkun, o si ni ibinujẹ pupọ ati àrun ati irora rẹ̀.

18 Kiyesi eyi ti mo ri: o dara o si yẹ fun enia, ki o jẹ, ki o si mu, ki o si ma jẹ alafia ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn, ni iye ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, ti Ọlọrun fi fun u: nitori eyi ni ipin tirẹ̀.

19 Bi Ọlọrun ba fi ọrọ̀ fun ẹnikẹni, ti o si fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀: ati lati mu ipin rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu lãla rẹ eyi; pẹlu ẹ̀bun Ọlọrun ni.

20 Nitoriti kì yio ranti ọjọ aiye rẹ̀ pọju; nitoriti Ọlọrun da a lohùn ninu ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12