1 EMI wi ninu mi pe, wá na! emi o fi iré-ayọ̀ dan ọ wò, nitorina mã jẹ afẹ! si kiyesi i, asan li eyi pẹlu!
2 Emi wi fun ẹrin pe, Iwère ni ọ: ati fun iré-ayọ̀ pe kili o nṣe?
3 Mo rò ninu aiya mi lati fi ọti-waini mu ara mi le, ṣugbọn emi nfi ọgbọ́n tọ́ aiya mi: on ati fi ọwọ le iwère, titi emi o fi ri ohun ti o dara fun ọmọ enia, ti nwọn iba mã ṣe labẹ ọrun ni iye ọjọ aiye wọn gbogbo.
4 Mo ṣe iṣẹ nla fun ara mi; mo kọ́ ile pupọ fun ara mi; mo gbin ọgbà-ajara fun ara mi.
5 Mo ṣe ọgbà ati agbala daradara fun ara mi, mo si gbin igi oniruru eso sinu wọn.
6 Mo ṣe adagun pupọ, lati ma bomi lati inu wọn si igbo ti o nmu igi jade wá:
7 Mo ni iranṣẹ-kọnrin ati iranṣẹ-birin, mo si ni ibile; mo si ni ini agbo malu ati agutan nlanla jù gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ṣaju mi.
8 Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ.
9 Bẹ̃ni mo tobi, mo si pọ̀ si i jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju mi ni Jerusalemu: ọgbọ́n mi si mbẹ pẹlu mi.
10 Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi.
11 Nigbati mo wò gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati lãla ti mo ṣe lãla lati ṣe: si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, ko si si ère kan labẹ õrùn.
12 Mo si yi ara mi pada lati wò ọgbọ́n, ati isinwin ati iwère: nitoripe kili ọkunrin na ti mbọ lẹhin ọba yio le ṣe? eyi ti a ti ṣe tan nigbani ni yio ṣe.
13 Nigbana ni mo ri pe ọgbọ́n ta wère yọ, to iwọn bi imọlẹ ti ta òkunkun yọ.
14 Oju ọlọgbọ́n mbẹ li ori rẹ̀; ṣugbọn aṣiwère nrìn li òkunkun: emitikalami si mọ̀ pẹlu pe, iṣe kanna li o nṣe gbogbo wọn.
15 Nigbana ni mo wi li aiya mi pe, Bi o ti nṣe si aṣiwère, bẹ̃li o si nṣe si emitikalami; nitori kili emi si ṣe gbọ́n jù? Nigbana ni mo wi li ọkàn mi pe, asan li eyi pẹlu.
16 Nitoripe iranti kò si fun ọlọgbọ́n pẹlu aṣiwère lailai; ki a wò o pe, bi akoko ti o kọja, bẹ̃li ọjọ ti mbọ, a o gbagbe gbogbo rẹ̀. Ọlọgbọ́n ha ṣe nkú bi aṣiwère?
17 Nitorina mo korira ìwa-laiye: nitoripe iṣẹ ti a ṣe labẹ õrun: ibi ni fun mi: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo.
18 Nitõtọ mo korira gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn: nitoriti emi o fi i silẹ fun enia ti mbọ̀ lẹhin mi.
19 Tali o si mọ̀ bi ọlọgbọ́n ni yio ṣe tabi aṣiwère? sibẹ on ni yio ṣe olori iṣẹ mi gbogbo ninu eyi ti mo ṣe lãla, ati ninu eyi ti mo fi ara mi hàn li ọlọgbọ́n labẹ õrùn. Asan li eyi pẹlu.
20 Nitorina mo kirilọ lati mu aiya mi ṣí kuro ninu gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn.
21 Nitoriti enia kan mbẹ, iṣẹ ẹniti o wà li ọgbọ́n ati ni ìmọ, ati ni iṣedẽde; sibẹ ẹniti kò ṣe lãla ninu rẹ̀ ni yio fi i silẹ fun ni ipin rẹ̀. Eyi pẹlu asan ni ati ibi nlanla.
22 Nitoripe kili enia ni ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o fi nṣe lãla labẹ õrùn?
23 Nitoripe ọjọ rẹ̀ gbogbo, ikãnu ni, ati iṣẹ rẹ̀, ibinujẹ, nitõtọ aiya rẹ̀ kò simi li oru. Eyi pẹlu asan ni.
24 Kò si ohun ti o dara fun enia jù ki o jẹ, ki o si mu ati ki o mu ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere ninu lãla rẹ̀. Eyi ni mo ri pẹlu pe, lati ọwọ Ọlọrun wá ni.
25 Nitoripe tali o le jẹun, tabi tani pẹlu ti o le mọ̀ adùn jù mi lọ?
26 Nitoripe Ọlọrun fun enia ti o tọ li oju rẹ̀ li ọgbọ́n, ati ìmọ ati ayọ̀: ṣugbọn ẹlẹṣẹ li o fi ìṣẹ́ fun, lati ma kó jọ ati lati ma tò jọ ki on ki o le ma fi fun ẹni rere niwaju Ọlọrun. Eyi pẹlu asan ni ati imulẹmofo.