1 Ọ̀RỌ Lemueli, ọba, ọ̀rọ-ẹkọ́ ti ìya rẹ̀ kọ́ ọ.
2 Kini, ọmọ mi? ki si ni, ọmọ inu mi? ati kini, ọmọ ẹ̀jẹ́ mi?
3 Máṣe fi agbara rẹ fun awọn obinrin, tabi ìwa rẹ fun awọn obinrin ti mbà awọn ọba jẹ.
4 Kì iṣe fun awọn ọba, Lemueli, kì iṣe fun awọn ọba lati mu ọti-waini; bẹ̃ni kì iṣe fun awọn ọmọ alade lati fẹ ọti lile:
5 Ki nwọn ki o má ba mu, nwọn a si gbagbe ofin, nwọn a si yi idajọ awọn olupọnju.
6 Fi ọti lile fun ẹniti o mura tan lati ṣegbe, ati ọti-waini fun awọn oninu bibajẹ.
7 Jẹ ki o mu, ki o si gbagbe aini rẹ̀, ki o má si ranti òṣi rẹ̀ mọ́.
8 Yà ẹnu rẹ fun ayadi, ninu ọ̀ran gbogbo ẹniti iṣe ọmọ iparun.
9 Yà ẹnu rẹ, fi ododo ṣe idajọ, ki o si gbèja talaka ati alaini.
10 Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn.
11 Aiya ọkọ rẹ̀ gbẹkẹle e laibẹ̀ru, bẹ̃ni on kì yio ṣe alaini ère iṣẹ.
12 Rere li obinrin na yio ma ṣe fun u, kì iṣe buburu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.
13 Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọ̀gbọ, o si fi ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ tinutinu.
14 O dabi ọkọ̀ oniṣowo: o si mu onjẹ rẹ̀ lati ọ̀na jijin rére wá.
15 On a si dide nigbati ilẹ kò ti imọ́, a si fi onjẹ fun enia ile rẹ̀, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbinrin rẹ̀.
16 O kiyesi oko, o si mu u: ère ọwọ rẹ̀ li o fi gbin ọgbà-ajara.
17 O fi agbara gbá ẹ̀gbẹ rẹ̀ li ọjá, o si mu apa rẹ̀ mejeji le.
18 O kiyesi i pe ọjà on dara: fitila rẹ̀ kò kú li oru.
19 O fi ọwọ rẹ̀ le kẹkẹ́-owú, ọwọ rẹ̀ si di ìranwu mu.
20 O nà ọwọ rẹ̀ si talaka; nitõtọ, ọwọ rẹ̀ si kàn alaini.
21 On kò si bẹ̀ru òjo-didì fun awọn ara ile rẹ̀; nitoripe gbogbo awọn ara ile rẹ̀ li a wọ̀ li aṣọ iṣẹpo meji.
22 On si wun aṣọ titẹ́ fun ara rẹ̀; ẹ̀wu daradara ati elese aluko li aṣọ rẹ̀.
23 A mọ̀ ọkọ rẹ̀ li ẹnu-bode, nigbati o ba joko pẹlu awọn àgba ilẹ na.
24 O da aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si tà a, pẹlupẹlu o fi ọjá amure fun oniṣòwo tà.
25 Agbara ati iyìn li aṣọ rẹ̀; on o si yọ̀ si ọjọ ti mbọ.
26 O fi ọgbọ́n yà ẹnu rẹ̀; ati li ahọn rẹ̀ li ofin iṣeun.
27 O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rẹ̀, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ.
28 Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u.
29 Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ.
30 Oju daradara li ẹ̀tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obinrin ti o bẹ̀ru Oluwa, on ni ki a fi iyìn fun.
31 Fi fun u ninu eso-iṣẹ ọwọ rẹ̀; jẹ ki iṣẹ ọwọ ara rẹ̀ ki o si yìn i li ẹnu-bodè.