Owe 1 YCE

Anfaani Àwọn Owe

1 OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli;

2 Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye;

3 Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe;

4 Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu.

5 Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n:

6 Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn.

Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́

7 Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́.

8 Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ:

9 Nitoripe awọn ni yio ṣe ade ẹwà fun ori rẹ, ati ọṣọ́ yi ọrùn rẹ ka.

10 Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà.

11 Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi.

12 Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati awọn ẹni-diduroṣinṣin bi awọn ti nlọ sinu iho:

13 Awa o ri onirũru ọrọ̀ iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa:

14 Dà ipin rẹ pọ̀ mọ arin wa; jẹ ki gbogbo wa ki a jọ ni àpo kan:

15 Ọmọ mi, máṣe rìn li ọ̀na pẹlu wọn: fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọ̀na wọn.

16 Nitori ti ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ.

17 Nitõtọ, lasan li a nà àwọn silẹ li oju ẹiyẹkẹiyẹ.

18 Awọn wọnyi si ba fun ẹ̀jẹ ara wọn; nwọn lumọ nikọkọ fun ẹmi ara wọn.

19 Bẹ̃ni ọ̀na gbogbo awọn ti nṣe ojukokoro ère; ti ngba ẹmi awọn oluwa ohun na.

Ọgbọ́n Ń pè

20 Ọgbọ́n nkigbe lode; o nfọhùn rẹ̀ ni igboro:

21 O nke ni ibi pataki apejọ, ni gbangba ẹnubode ilu, o sọ ọ̀rọ rẹ̀ wipe,

22 Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọ̀kan ti ẹnyin o fi ma fẹ aimọ̀kan? ati ti awọn ẹlẹgàn yio fi ma ṣe inudidùn ninu ẹ̀gan wọn, ati ti awọn aṣiwere yio fi ma korira ìmọ?

23 Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi i, emi o dà ẹmi mi sinu nyin, emi o fi ọ̀rọ mi hàn fun nyin.

24 Nitori ti emi pè, ti ẹnyin si kọ̀; ti emi nà ọwọ mi, ti ẹnikan kò si kà a si:

25 Ṣugbọn ẹnyin ti ṣá gbogbo ìgbimọ mi tì, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi:

26 Emi pẹlu o rẹrin idãmu nyin; emi o ṣe ẹ̀fẹ nigbati ibẹ̀ru nyin ba de;

27 Nigbati ibẹ̀ru nyin ba de bi ìji, ati idãmu nyin bi afẹyika-ìji; nigbati wahala ati àrodun ba de si nyin.

28 Nigbana ni ẹnyin o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o ṣafẹri mi ni kùtukùtu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi:

29 Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa.

30 Nwọn kò fẹ ìgbimọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi.

31 Nitorina ni nwọn o ṣe ma jẹ ninu ère ìwa ara wọn, nwọn o si kún fun ìmọkimọ wọn.

32 Nitoripe irọra awọn alaimọ̀kan ni yio pa wọn, ati alafia awọn aṣiwere ni yio pa wọn run.

33 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fetisi mi yio ma gbe lailewu, yio si farabalẹ kuro ninu ibẹ̀ru ibi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31