Owe 13 YCE

1 ỌLỌGBỌ́N ọmọ gbà ẹkọ́ baba rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹgàn kò gbọ́ ibawi.

2 Enia yio jẹ rere nipa ère ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ifẹ ọkàn awọn olurekọja ni ìwa-agbara.

3 Ẹniti o pa ẹnu rẹ̀ mọ́, o pa ẹmi rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ṣi ète rẹ̀ pupọ yio ni iparun.

4 Ọkàn ọlẹ nfẹ, kò si ri nkan; ṣugbọn ọkàn awọn alãpọn li a o mu sanra.

5 Olododo korira ẹ̀tan; ṣugbọn enia buburu mu ni hu ìwa irira on itiju.

6 Ododo pa aduro-ṣinṣin li ọ̀na mọ́; ṣugbọn ìwa-buburu ni imuni ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.

7 Ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe ọlọrọ̀, ṣugbọn kò ni nkan; ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe talaka ṣugbọn o li ọrọ̀ pupọ.

8 Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi.

9 Imọlẹ olododo nfi ayọ̀ jó; ṣugbọn fitila enia buburu li a o pa.

10 Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà.

11 Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i.

12 Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni.

13 Ẹnikan ti o ba gàn ọ̀rọ na li a o parun: ṣugbọn ẹniti o bẹ̀ru ofin na, li a o san pada fun.

14 Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú.

15 Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọ̀na awọn olurekọja ṣoro.

16 Gbogbo amoye enia ni nfi ìmọ ṣiṣẹ; ṣugbọn aṣiwere tan were rẹ̀ kalẹ.

17 Oniṣẹ buburu bọ́ sinu ipọnju; ṣugbọn olõtọ ikọ̀ mu ilera wá.

18 Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun.

19 Ifẹ ti a muṣẹ dùnmọ ọkàn; ṣugbọn irira ni fun aṣiwere lati kuro ninu ibi.

20 Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe.

21 Ibi nlepa awọn ẹlẹṣẹ̀; ṣugbọn fun awọn olododo, rere li a o ma fi san a.

22 Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo,

23 Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ;

24 Ẹniti o ba fà ọwọ paṣan sẹhin, o korira ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o fẹ ẹ a ma tète nà a.

25 Olododo jẹ to itẹrun ọkàn rẹ̀; ṣugbọn inu awọn enia buburu ni yio ṣe alaini.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31