Owe 22 YCE

1 ORUKỌ rere sàn ni yiyàn jù ọrọ̀ pupọ lọ, ati ojurere ifẹ jù fadaka ati wura lọ.

2 Ọlọrọ̀ ati talaka pejọ pọ̀: Oluwa li ẹlẹda gbogbo wọn.

3 Ọlọgbọ́n enia ti ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́: ṣugbọn awọn òpe a kọja, a si jẹ wọn niya.

4 Ere irẹlẹ ati ibẹ̀ru Oluwa li ọrọ̀, ọlá, ati ìye.

5 Ẹgún ati idẹkùn mbẹ li ọ̀na alayidayida: ẹniti o ba pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yio jina si wọn.

6 Tọ́ ọmọde li ọ̀na ti yio tọ̀: nigbati o si dàgba tan, kì yio kuro ninu rẹ̀.

7 Ọlọrọ̀ ṣe olori olupọnju, ajigbese si ṣe iranṣẹ fun onigbese.

8 Ẹniti o ba funrugbin ẹ̀ṣẹ, yio ri asan ka: ọpá ibinu rẹ̀ si ti mura tan.

9 Ẹniti o li oju ãnu li a o bukun fun; nitoriti o fi ninu onjẹ rẹ̀ fun olupọnju.

10 Ṣá ẹlẹgàn tì sode, ìja yio si jade; nitõtọ ìja ati ẹ̀gan yio dẹkun.

11 Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀.

12 Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po.

13 Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro.

14 Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀.

15 Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀.

16 Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe.

Ọgbọ̀n Gbolohun tí Ọlọ́gbọ́n Sọ

17 Dẹti rẹ silẹ, ki o gbọ́ ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n, ki o si fi aiya rẹ si ẹkọ́ mi.

18 Nitori ohun didùn ni bi iwọ ba pa wọn mọ́ ni inu rẹ; nigbati a si pese wọn tan li ète rẹ.

19 Ki igbẹkẹle rẹ ki o le wà niti Oluwa, emi fi hàn ọ loni, ani fun ọ.

20 Emi kò ti kọwe ohun daradara si ọ ni igbimọ ati li ẹkọ́,

21 Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ?

22 Máṣe ja talaka li ole, nitori ti iṣe talaka: bẹ̃ni ki o má si ṣe ni olupọnju lara ni ibode:

23 Nitori Oluwa yio gbija wọn, yio si gbà ọkàn awọn ti ngbà lọwọ wọn.

24 Máṣe ba onibinu enia ṣe ọrẹ́; má si ṣe ba ọkunrin oninu-fùfu rìn.

25 Ki iwọ ki o má ba kọ́ ìwa rẹ̀, iwọ a si gbà ikẹkùn fun ara rẹ.

26 Máṣe wà ninu awọn ti nṣe igbọwọ, tabi ninu awọn ti o duro fun gbèse.

27 Bi iwọ kò ba ni nkan ti iwọ o fi san, nitori kini yio ṣe gbà ẹní rẹ kuro labẹ rẹ?

28 Máṣe yẹ̀ àla ilẹ igbàni, ti awọn baba rẹ ti pa.

29 Iwọ ri enia ti o nfi aiṣemẹlẹ ṣe iṣẹ rẹ̀? on o duro niwaju awọn ọba; on kì yio duro niwaju awọn enia lasan.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31