1 IDAHÙN pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ lile ni irú ibinu soke.
2 Ahọn ọlọgbọ́n nlò ìmọ rere: ṣugbọn ẹnu aṣiwère a ma gufẹ wère.
3 Oju Oluwa mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere.
4 Ahọn imularada ni igi ìye: ṣugbọn ayidayida ninu rẹ̀ ni ibajẹ ọkàn.
5 Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye.
6 Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu.
7 Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃.
8 Ẹbọ awọn enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn adura awọn aduroṣinṣin ni didùn-inu rẹ̀.
9 Ọ̀na enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn o fẹ ẹniti ntọ̀ ododo lẹhin.
10 Ikilọ kikan wà fun ẹniti o kọ̀ ọ̀na silẹ; ẹniti o ba si korira ibawi yio kú.
11 Ipo-okú ati iparun ṣi silẹ niwaju Oluwa; njẹ melomelo li aiya awọn ọmọ enia.
12 Ẹlẹgàn kò fẹ ẹniti mba a wi; bẹ̃ni kì yio tọ̀ awọn ọlọgbọ́n lọ.
13 Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi.
14 Aiya ẹniti oye ye nṣe afẹri ìmọ; ṣugbọn ẹnu aṣiwère nfi wère bọ́ ara rẹ̀.
15 Gbogbo ọjọ olupọnju ni ibi; ṣugbọn oninu-didùn njẹ alafia nigbagbogbo.
16 Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀.
17 Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀.
18 Abinu enia rú asọ̀ soke; ṣugbọn ẹniti o lọra ati binu, o tù ìja ninu.
19 Ọna ọlẹ dabi igbo ẹgún; ṣugbọn ọ̀na olododo já gẽrege ni.
20 Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe ayọ̀ baba; ṣugbọn aṣiwère enia gàn iya rẹ̀.
21 Ayọ̀ ni wère fun ẹniti oye kù fun; ṣugbọn ẹni-oye a ma rìn ni iduroṣinṣin.
22 Laisi ìgbimọ, èro a dasan; ṣugbọn li ọ̀pọlọpọ ìgbimọ, nwọn a fi idi mulẹ.
23 Enia ni ayọ̀ nipa idahùn ẹnu rẹ̀; ati ọ̀rọ kan li akoko rẹ̀, o ti wọ̀ to?
24 Ọ̀na ìye lọ soke fun ọlọgbọ́n, ki o le kuro ni ipo-okú nisalẹ.
25 Oluwa yio run ile agberaga; ṣugbọn yio fi ìpãlà opó kalẹ.
26 Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀.
27 Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè.
28 Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade.
29 Oluwa jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbọ́ adura awọn olododo.
30 Imọlẹ oju mu inu dùn; ihin rere si mu egungun sanra.
31 Ẹniti o ba gbọ́ ibawi ìye, a joko lãrin awọn ọlọgbọ́n.
32 Ẹniti o kọ̀ ẹkọ́, o gàn ọkàn ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba gbọ́ ibawi, o ni imoye.
33 Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.