Owe 18 YCE

1 ẸNITI o yà ara rẹ̀ sọtọ̀ yio lepa ifẹ ara rẹ̀, yio si kọju ìja nla si ohunkohun ti iṣe ti oye.

2 Aṣiwère kò ni inu-didùn si imoye, ṣugbọn ki o le fi aiya ara rẹ̀ hàn.

3 Nigbati enia-buburu ba de, nigbana ni ẹ̀gan de, ati pẹlu ẹ̀gan ni itiju.

4 Ọ̀rọ ẹnu enia dabi omi jijìn, orisun ọgbọ́n bi odò ṣiṣàn.

5 Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ.

6 Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá.

7 Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀.

8 Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.

9 Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni.

10 Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.

11 Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀.

12 Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ.

13 Ẹniti o ba dahùn ọ̀rọ ki o to gbọ́, wère ati itiju ni fun u.

14 Ọkàn enia yio faiyàrán ailera rẹ̀; ṣugbọn ọkàn ti o rẹ̀wẹsi, tani yio gbà a?

15 Aiya amoye ni ìmọ; eti ọlọgbọ́n a si ma ṣe afẹri ìmọ.

16 Ọrẹ enia a ma fi àye fun u, a si mu u wá siwaju awọn enia nla.

17 Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ.

18 Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.

19 Arakunrin ti a ṣẹ̀ si, o ṣoro jù ilu olodi lọ: ìja wọn si dabi ọpá idabu ãfin.

20 Ọ̀rọ ẹnu enia ni yio mu inu rẹ̀ tutu: ibisi ẹnu rẹ̀ li a o si fi tù u ninu.

21 Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀.

22 Ẹnikẹni ti o ri aya fẹ, o ri ohun rere, o si ri ojurere lọdọ Oluwa.

23 Talaka a ma bẹ̀ ẹ̀bẹ; ṣugbọn ọlọrọ̀ a ma fi ikanra dahùn.

24 Ẹniti o ni ọrẹ́ pupọ, o ṣe e si iparun ara rẹ̀; ọrẹ́ kan si mbẹ ti o fi ara mọni ju arakunrin lọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31