Owe 21 YCE

1 AIYA ọba mbẹ lọwọ Oluwa bi odò omi; on a si dari rẹ̀ si ìbikibi ti o wù u.

2 Gbogbo ọ̀na enia li o dara li oju ara rẹ̀: ṣugbọn Oluwa li o nṣe amọ̀na ọkàn.

3 Lati ṣe ododo ati idajọ, o ṣe itẹwọgba fun Oluwa jù ẹbọ lọ.

4 Gangan oju, ati igberaga aiya, ati itulẹ̀ enia buburu, ẹ̀ṣẹ ni.

5 Ìronu alãpọn si kiki ọ̀pọ ni; ṣugbọn ti olukuluku ẹniti o yara, si kiki aini ni.

6 Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹ ẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri.

7 Iwa-agbara awọn enia buburu ni yio pa wọn run: nitori ti nwọn kọ̀ lati ṣe idajọ.

8 Ẹnikẹni ti o nrìn ọ̀na ayidayida, enia buburu ni; ṣugbọn oninu funfun ni iṣẹ rẹ̀ tọ́.

9 O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.

10 Ọkàn enia buburu nwá ibi kiri: aladugbo rẹ̀ kò ri ojurere li oju rẹ̀.

11 Nigbati a ba jẹ ẹlẹgàn ni ìya, a sọ òpe di ọlọgbọ́n: nigbati a ba si nkọ́ ọlọgbọ́n, on o ma ni ìmọ.

12 Olododo kiyesi ile enia buburu: pe ẹnikan wà ti yio bì enia buburu ṣubu sinu iparun.

13 Ẹnikẹni ti o ba di eti rẹ̀ si igbe olupọnju, ontikararẹ̀ yio ke pẹlu: ṣugbọn a kì yio gbọ́.

14 Ọrẹ ikọkọ, o tù ibinu: ati ẹ̀bun ni iṣẹpo-aṣọ, o tù ibinu lile.

15 Ayọ̀ ni fun olododo lati ṣe idajọ: ṣugbọn iparun ni fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

16 Ẹniti o ba yà kuro li ọ̀na oye, yio ma gbe inu ijọ awọn okú.

17 Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀.

18 Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin.

19 O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ.

20 Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ.

21 Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá.

22 Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀.

23 Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu.

24 Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ.

25 Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe.

26 O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro.

27 Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀?

28 Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu.

29 Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀.

30 Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa.

31 A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31