Owe 23 YCE

1 NIGBATI iwọ ba joko lati ba ijoye jẹun, kiyesi ẹniti o wà niwaju rẹ gidigidi.

2 Ki o si fi ọbẹ le ara rẹ li ọfun, bi iwọ ba iṣe okundùn enia.

3 Máṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀: nitoripe onjẹ ẹ̀tan ni.

4 Máṣe lãla ati lọrọ̀: ṣiwọ kuro ninu imoye ara rẹ.

5 Iwọ o ha fi oju rẹ wò o? kì yio si si mọ, nitoriti ọrọ̀ hu iyẹ-apá fun ara rẹ̀ bi ìdi ti nfò li oju ọrun.

6 Máṣe jẹ onjẹ oloju buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀.

7 Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ li o ri: mã jẹ, ki o si ma mu li o nwi fun ọ; ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò pẹlu rẹ.

8 Okele ti iwọ jẹ ni iwọ o pọ̀ jade, iwọ a si sọ ọ̀rọ didùn rẹ nù.

9 Máṣe sọ̀rọ li eti aṣiwère: nitoriti yio gàn ọgbọ́n ọ̀rọ rẹ.

10 Máṣe ṣi àla atijọ; má si ṣe bọ sinu oko alaini-baba.

11 Nitoripe Olurapada wọn lagbara; yio gbà ìja wọn ja ti awọn tirẹ.

12 Fi aiya si ẹkọ́, ati eti rẹ si ọ̀rọ ìmọ.

13 Máṣe fà ọwọ ibawi sẹhin kuro lara ọmọde, nitoripe bi iwọ ba fi paṣan nà a, on kì yio kú.

14 Iwọ fi paṣan nà a, iwọ o si gbà ọkàn rẹ̀ la kuro li ọrun-apadi.

15 Ọmọ mi, bi ọkàn rẹ ba gbọ́n ọkàn mi yio yọ̀, ani emi pẹlu.

16 Inu mi yio si dùn nigbati ètè rẹ ba nsọ̀rọ titọ.

17 Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo.

18 Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro.

19 Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki iwọ ki o si gbọ́n, ki iwọ ki o si ma tọ́ aiya rẹ si ọ̀na titọ.

20 Máṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn ti mba ẹran-ara awọn tikarawọn jẹ.

21 Nitoripe ọmuti ati ọjẹun ni yio di talaka; ọlẹ ni yio si fi akisa bò ara rẹ̀.

22 Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó.

23 Ra otitọ, ki o má si ṣe tà a; ọgbọ́n pẹlu ati ẹkọ́, ati imoye.

24 Baba olododo ni yio yọ̀ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọ́n, yio ni ayọ̀ ninu rẹ̀.

25 Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.

26 Ọmọ mi, fi aiya rẹ fun mi, ki o si jẹ ki oju rẹ ki o ni inu-didùn si ọ̀na mi.

27 Nitoripe agbere, iho jijin ni; ati ajeji obinrin, iho hiha ni.

28 On a si ba ni ibuba bi ole, a si sọ awọn olurekọja di pupọ ninu awọn enia.

29 Tali o ni òṣi? tali o ni ibinujẹ? tali o ni ijà? tali o ni asọ̀? tali o ni ọgbẹ lainidi, tali o ni oju pipọn.

30 Awọn ti o duro pẹ nibi ọti-waini; awọn ti nlọ idan ọti-waini àdalu wò.

31 Iwọ máṣe wò ọti-waini pe o pọn, nigbati o ba fi àwọ rẹ̀ han ninu ago, ti a ngbe e mì, ti o ndùn.

32 Nikẹhin on a buniṣán bi ejò, a si bunijẹ bi paramọlẹ.

33 Oju rẹ yio wò awọn ajeji obinrin, aiya rẹ yio si sọ̀rọ ayidayida.

34 Nitõtọ, iwọ o dabi ẹniti o dubulẹ li arin okun, tabi ẹniti o dubulẹ lòke òpó-ọkọ̀.

35 Iwọ o si wipe, nwọn lù mi; kò dùn mi; nwọn lù mi, emi kò si mọ̀: nigbawo li emi o ji? emi o tun ma wá a kiri.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31