Owe 2 YCE

Èrè Tó Wà ninu Ọgbọ́n

1 ỌMỌ mi, bi iwọ ba fẹ igba ọ̀rọ mi, ki iwọ si pa ofin mi mọ́ pẹlu rẹ.

2 Ti iwọ dẹti rẹ silẹ si ọgbọ́n, ti iwọ si fi ọkàn si oye;

3 Ani bi iwọ ba nke tọ̀ ìmọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohùn rẹ soke fun oye;

4 Bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ́;

5 Nigbana ni iwọ o mọ̀ ibẹ̀ru Oluwa, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun.

6 Nitori Oluwa ni ifi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ ati oye ti iwá.

7 O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede.

8 O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́.

9 Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere.

10 Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ;

11 Imoye yio pa ọ mọ́, oye yio si ma ṣọ́ ọ:

12 Lati gbà ọ li ọwọ ẹni-ibi, li ọwọ ọkunrin ti nsọrọ ayidayida;

13 Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun;

14 Ẹniti o yọ̀ ni buburu iṣe, ti o ṣe inu-didùn si ayidàyidà awọn enia buburu;

15 Ọ̀na ẹniti o wọ́, nwọn si ṣe arekereke ni ipa-ọ̀na wọn:

16 Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni;

17 Ẹniti o kọ̀ ọrẹ́ igbà-ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀.

18 Nitoripe ile rẹ̀ tẹ̀ sinu ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ awọn okú.

19 Kò si ẹniti o tọ̀ ọ lọ ti o si tun pada sẹhin, bẹ̃ni nwọn kì idé ipa-ọ̀na ìye.

20 Ki iwọ ki o le ma rin li ọ̀na enia rere, ki iwọ ki o si pa ọ̀na awọn olododo mọ́.

21 Nitoripe ẹni-iduroṣinṣin ni yio joko ni ilẹ na, awọn ti o pé yio si ma wà ninu rẹ̀.

22 Ṣugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro ni ilẹ aiye, ati awọn olurekọja li a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31