1 ẸNITI a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe.
2 Nigbati awọn olododo wà lori oyè, awọn enia a yọ̀; ṣugbọn nigbati enia buburu ba gori oyè, awọn enia a kẹdùn.
3 Ẹnikẹni ti o fẹ ọgbọ́n, a mu baba rẹ̀ yọ̀: ṣugbọn ẹniti o mba panṣaga kẹgbẹ, a ba ọrọ̀ rẹ̀ jẹ.
4 Nipa idajọ li ọba imu ilẹ tòro: ṣugbọn ẹniti o ba ngbà ọrẹ a bì i ṣubu.
5 Ẹniti o npọ́n ẹnikeji rẹ̀ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rẹ̀.
6 Ninu irekọja enia ibi, ikẹkùn mbẹ: ṣugbọn olododo a ma kọrin, a si ma yọ̀.
7 Olododo a ma rò ọ̀ran talaka: ṣugbọn enia buburu kò ṣú si i lati rò o.
8 Awọn ẹlẹgàn enia da irukerudo si ilu: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n enia ṣẹ́ri ibinu kuro.
9 Ọlọgbọ́n enia ti mba aṣiwère enia ja, bi inu li o mbi, bi ẹrín li o nrín, isimi kò si.
10 Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀.
11 Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin.
12 Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru.
13 Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji.
14 Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai.
15 Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀.
16 Nigbati awọn enia buburu ba npọ̀ si i, irekọja a pọ̀ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn.
17 Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn.
18 Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́.
19 A kì ifi ọ̀rọ kilọ fun ọmọ-ọdọ; bi o tilẹ ye e kì yio dahùn.
20 Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
21 Ẹniti o ba fi ikẹ́ tọ́ ọmọ-ọdọ rẹ̀ lati igba-ewe wá, oun ni yio jogún rẹ̀.
22 Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja.
23 Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá.
24 Ẹniti o kó ẹgbẹ ole korira ọkàn ara rẹ̀: o ngbọ́ ifiré, kò si fihan.
25 Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke.
26 Ọpọlọpọ enia li o nwá ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ enia li o nti ọdọ Oluwa wá.
27 Alaiṣõtọ enia, irira ni si awọn olododo: ẹniti o si ṣe aduro-ṣinṣin li ọ̀na, irira ni si enia buburu.