Owe 30 YCE

Àwọn Ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ

1 Ọ̀RỌ Aguri, ọmọ Jake, ọ̀rọ ẹkọ́ ti ọkunrin na ti sọ, fun Itieli, ani fun Itieli ati Ukali.

2 Nitõtọ emi ṣiwère jù ẹlomiran lọ, emi kò si ni imoye enia.

3 Emi kò tilẹ kọ́ ọgbọ́n, emi kò tilẹ ni ìmọ ohun mimọ́.

4 Tali o ti gòke lọ si ọrun, tabi ti o si sọkalẹ wá? tali o kó afẹfẹ jọ li ọwọ rẹ̀? tali o di omi sinu aṣọ; tali o fi gbogbo opin aiye le ilẹ? Orukọ rẹ̀ ti ijẹ, ati orukọ ọmọ rẹ̀ ti ijẹ, bi iwọ ba le mọ̀ ọ?

5 Gbogbo ọ̀rọ Oluwa jẹ́ otitọ: on li asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.

6 Iwọ máṣe fi kún ọ̀rọ rẹ̀, ki on má ba ba ọ wi, a si mu ọ li eke.

Àwọn Òwe Mìíràn

7 Ohun meji ni mo tọrọ lọdọ rẹ; máṣe fi wọn dù mi ki emi to kú.

8 Mu asan ati eke jìna si mi: máṣe fun mi li òṣi, máṣe fun mi li ọrọ̀; fi onjẹ ti o to fun mi bọ mi.

9 Ki emi ki o má ba yó jù, ki emi ki o má si sẹ́ ọ, pe ta li Oluwa? tabi ki emi má ba tòṣi, ki emi si jale, ki emi si ṣẹ̀ si orukọ Ọlọrun mi.

10 Máṣe fi iranṣẹ sùn oluwa rẹ̀, ki o má ba fi ọ bu, ki iwọ má ba jẹbi.

11 Iran kan wà ti nfi baba rẹ̀ bu, ti kò si sure fun iya rẹ̀.

12 Iran kan wà, ti o mọ́ li oju ara rẹ̀, ṣugbọn a kò ti iwẹ̀ ẹ nù kuro ninu ẽri rẹ̀.

13 Iran kan wà, yẽ, oju rẹ̀ ti gbega to! ipenpeju rẹ̀ si gbé soke.

14 Iran kan wà, ehin ẹniti o dabi idà, erigi rẹ̀ dabi ọbẹ, lati jẹ talaka run kuro lori ilẹ, ati awọn alaini kuro ninu awọn enia.

15 Eṣúṣu ni ọmọbinrin meji, ti nkigbe pe, Muwá, muwá. Ohun mẹta ni mbẹ ti a kò le tẹ lọrùn lai, ani mẹrin kì iwipe, o to.

16 Isa-okú, ati inu àgan; ilẹ ti kì ikún fun omi; ati iná ti kì iwipe, o to.

17 Oju ti o sin baba rẹ̀ jẹ, ti o gàn ati gbọ́ ti iya rẹ̀, kanakáná ẹba odò ni yio yọ ọ jade, ọmọ idì a si mu u jẹ.

18 Ohun mẹta ni mbẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitõtọ, mẹrin li emi kò mọ̀.

19 Ipa idì loju ọrun; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju okun; ati ìwa ọkunrin pẹlu wundia.

20 Bẹ̃ni ìwa agbere obinrin: o jẹun, o si nù ẹnu rẹ̀ nù, o si wipe, emi kò ṣe buburu kan.

21 Nitori ohun mẹta, aiye a di rũru, ati labẹ mẹrin ni kò le duro.

22 Iranṣẹ, nigbati o jọba; ati aṣiwère, nigbati o yo fun onjẹ;

23 Fun obinrin, ti a korira, nigbati a sọ ọ di iyale; ati fun iranṣẹbinrin, nigbati o di arole iya rẹ̀.

24 Ohun mẹrin ni mbẹ ti o kerejù lori ilẹ, sibẹ nwọn gbọ́n, nwọn kọ́ni li ẹkọ́.

25 Alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba ẹ̀run.

26 Alailagbara enia li ehoro, ṣugbọn nwọn a ṣe ìho wọn ni ibi palapala okuta.

27 Awọn ẽṣú kò li ọba, sibẹ gbogbo wọn a jade lọ li ọwọ́-ọwọ́;

28 Ọmọle fi ọwọ rẹ̀ dì mu, o si wà li ãfin awọn ọba.

29 Ohun mẹta ni mbẹ ti nrìn rere, nitõtọ, mẹrin li o dára pupọ ni ìrin rirìn:

30 Kiniun ti o lagbara julọ ninu ẹranko, ti kò si pẹhinda fun ẹnikan;

31 Ẹṣin ti a dì lẹgbẹ; ati obukọ; ati ọba larin awọn enia rẹ̀.

32 Bi iwọ ba ti ṣiwère ni gbigbe ara rẹ soke, tabi bi iwọ ba ti ronú ibi, fi ọwọ rẹ le ẹnu rẹ.

33 Nitõtọ, mimì wàra ni imu orí-àmọ́ wá, ati fifun imu ni imu ẹ̀jẹ jade; bẹ̃ni riru ibinu soke ni imu ìja wá.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31