1 OWE Solomoni ni wọnyi. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe inu-didùn baba rẹ̀, ṣugbọn aṣiwere ọmọ ni ibanujẹ iya rẹ̀.
2 Iṣura ìwa-buburu kò li ère: ṣugbọn ododo ni igbani kuro lọwọ ikú.
3 Oluwa kì yio jẹ ki ebi ki o pa ọkàn olododo; ṣugbọn o yi ifẹ awọn enia buburu danu.
4 Ẹniti o ba dẹ̀ ọwọ a di talaka; ṣugbọn ọwọ awọn alãpọn ni imu ọlà wá.
5 Ẹniti o ba kojọ ni igba-ẹ̀run li ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ba nsùn ni igba ikore li ọmọ ti idoju tì ni.
6 Ibukún wà li ori olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu.
7 Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà.
8 Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun.
9 Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀.
10 Ẹniti nṣẹ́ oju o mu ibanujẹ wá: ṣugbọn ète werewere li a o parun.
11 Kanga ìye li ẹnu olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu.
12 Irira ni irú ìja soke: ṣugbọn ifẹ bò gbogbo ẹ̀ṣẹ mọlẹ.
13 Li ète ẹniti o moye li a ri ọgbọ́n: ṣugbọn kùmọ ni fun ẹhin ẹniti oye kù fun.
14 Awọn ọlọgbọ́n a ma to ìmọ jọ: ṣugbọn ẹnu awọn aṣiwere sunmọ iparun.
15 Ọrọ̀ ọlọlà ni agbára rẹ̀: aini awọn talaka ni iparun wọn.
16 Iṣẹ olododo tẹ̀ si ìye; èro awọn enia buburu si ẹ̀ṣẹ.
17 Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna.
18 Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni.
19 Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n.
20 Ahọn olõtọ dabi ãyo fadaka: aiya enia buburu kò ni iye lori.
21 Ete olododo mbọ́ ọ̀pọlọpọ enia: ṣugbọn awọn aṣiwere yio kú li ailọgbọ́n.
22 Ibukún Oluwa ni imu ni ilà, kì isi ifi lãla pẹlu rẹ̀.
23 Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye.
24 Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u.
25 Bi ìji ti ijà rekọja: bẹ̃li enia buburu kì yio si mọ: ṣugbọn olododo ni ipilẹ ainipẹkun.
26 Bi ọti kikan si ehin, ati bi ẽfin si oju, bẹ̃li ọlẹ si ẹniti o rán a ni iṣẹ.
27 Ibẹ̀ru Oluwa mu ọjọ gùn: ṣugbọn ọdun enia buburu li a o ṣẹ́ kuru.
28 Abá olododo ayọ̀ ni yio jasi: ṣugbọn ireti enia buburu ni yio ṣegbe.
29 Ọ̀na Oluwa jẹ́ ãbò fun ẹni iduroṣinṣin, ṣugbọn egbe ni fun awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ.
30 A kì yio ṣi olododo ni ipo lai; ṣugbọn enia buburu kì yio gbe ilẹ̀-aiye.
31 Ẹnu olõtọ mu ọgbọ́n jade; ṣugbọn ahọn arekereke li a o ke kuro.
32 Ete olododo mọ̀ ohun itẹwọgba; ṣugbọn ẹnu enia buburu nsọ̀rọ arekereke.