Owe 20 YCE

1 ẸLẸYA li ọti-waini, alariwo li ọti lile, ẹnikẹni ti a ba fi tanjẹ kò gbọ́n.

2 Ibẹ̀ru ọba dabi igbe kiniun: ẹnikẹni ti o ba mu u binu, o ṣẹ̀ si ọkàn ara rẹ̀.

3 Ọlá ni fun enia lati ṣiwọ kuro ninu ìja: ṣugbọn olukuluku aṣiwère ni ima ja ìja nla.

4 Ọlẹ kò jẹ tu ilẹ nitori otutu; nitorina ni yio fi ma ṣagbe nigba ikore, kì yio si ni nkan.

5 Ìmọ ninu ọkàn enia dabi omi jijin; ṣugbọn amoye enia ni ifà a jade.

6 Ọ̀pọlọpọ enia ni ima fọnrere, olukuluku ọrẹ ara rẹ̀: ṣugbọn olõtọ enia tani yio ri i.

7 Olõtọ enia nrìn ninu iwa-titọ rẹ̀: ibukún si ni fun awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀!

8 Ọba ti o joko lori itẹ́ idajọ, o fi oju rẹ̀ fọ́n ìwa-ibi gbogbo ka.

9 Tali o le wipe, Mo ti mu aiya mi mọ́, emi ti mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi?

10 Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, bakanna ni mejeji ṣe irira loju Oluwa.

11 Iṣe ọmọde pãpa li a fi imọ̀ ọ, bi ìwa rẹ̀ ṣe rere ati titọ.

12 Eti igbọ́ ati oju irí, Oluwa li o ti dá awọn mejeji.

13 Máṣe fẹ orun sisùn, ki iwọ ki o má ba di talaka; ṣi oju rẹ, a o si fi onjẹ tẹ ọ lọrùn.

14 Kò ni lãri, kò ni lãri li oníbárà iwi; ṣugbọn nigbati o ba bọ si ọ̀na rẹ̀, nigbana ni iṣogo.

15 Wura wà ati iyùn ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn ète ìmọ, èlo iyebiye ni.

16 Gba aṣọ rẹ̀, nitori ti o ṣe onigbọwọ fun alejo, si gba ohun ẹrí lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.

17 Onjẹ ẹ̀tan dùn mọ enia; ṣugbọn nikẹhin, ẹnu rẹ̀ li a o fi tarã kún.

18 Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun.

19 Ẹniti o ba nkiri bi olofofo a ma fi ọ̀ran ìkọkọ hàn: má si ṣe ba ẹniti nṣi ète rẹ̀ ṣire.

20 Ẹnikẹni ti o ba bú baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o pa ninu òkunkun biribiri.

21 Ogún ti a yara jẹ latetekọṣe, li a kì yio bukún li opin rẹ̀.

22 Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa, on o si gbà ọ.

23 Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, irira ni loju Oluwa; ìwọn irẹjẹ kò si dara.

24 Irin ti enia nrìn, lati ọdọ Oluwa ni; tani ninu awọn enia ti o le mọ̀ ọ̀na rẹ̀?

25 Idẹkùn ni fun enia lati yara ṣe ileri mimọ́, ati lẹhin ẹjẹ́, ki o ma ronu.

26 Ọlọgbọ́n ọba a tú enia buburu ka, a si mu ayika-kẹkẹ́ rẹ̀ kọja lori wọn.

27 Ẹmi enia ni fitila Oluwa, a ma ṣe awari iyara inu.

28 Anu ati otitọ pa ọba mọ́: ãnu li a si fi ndi itẹ́ rẹ̀ mu.

29 Ogo awọn ọdọmọkunrin li agbara wọn: ẹwà awọn arugbo li ewú.

30 Apá ọgbẹ ni iwẹ̀ ibi nù kuro: bẹ̃ si ni ìna ti o wọ̀ odò ikùn lọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31