Owe 28 YCE

1 ENIA buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun.

2 Nipa irekọja ilẹ li awọn ijoye idi pupọ, ṣugbọn nipa amoye ati oni ìmọ̀ enia kan, li a mu ilẹ pẹ.

3 Olupọnju ti o nni olupọnju lara, o dabi agbalọ òjo ti kò fi onjẹ silẹ.

4 Awọn ti o kọ̀ ofin silẹ a ma yìn enia buburu: ṣugbọn awọn ti o pa ofin mọ́ a ma binu si wọn.

5 Oye idajọ kò ye enia buburu: ṣugbọn awọn ti nṣe afẹri Oluwa moye ohun gbogbo.

6 Talaka ti nrin ninu iduro-ṣinṣin rẹ̀, o san jù alarekereke ìwa, bi o tilẹ ṣe ọlọrọ̀.

7 Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́, o ṣe ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ṣe ẹlẹgbẹ jẹguduragudu, o dojuti baba rẹ̀.

8 Ẹniti o fi elé ati ère aiṣõtọ sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di pupọ, o kó o jọ fun ẹniti yio ṣãnu fun awọn talaka.

9 Ẹniti o mu eti rẹ̀ kuro lati gbọ́ ofin, ani adura rẹ̀ pãpa yio di irira.

10 Ẹnikẹni ti o mu olododo ṣìna si ọ̀na buburu, ontikararẹ̀ yio bọ si iho, ṣugbọn aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere.

11 Ọlọrọ̀ gbọ́n li oju ara rẹ̀: ṣugbọn talaka ti o moye ridi rẹ̀.

12 Nigbati awọn olododo enia ba nyọ̀, ọṣọ́ nla a wà; ṣugbọn nigbati enia buburu ba dide, enia a sá pamọ́.

13 Ẹniti o bo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọlẹ kì yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ̀ ọ silẹ yio ri ãnu.

14 Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru nigbagbogbo: ṣugbọn ẹniti o ba sé aiya rẹ̀ le ni yio ṣubu sinu ibi.

15 Bi kiniun ti nke ramùramu, ati ẹranko beari ti nfi ebi sare kiri; bẹ̃ni ẹni buburu ti o joye lori awọn talaka.

16 Ọmọ-alade ti o ṣe alaimoye pupọ ni iṣe ìwa-ika pupọ pẹlu: ṣugbọn eyiti o korira ojukokoro yio mu ọjọ rẹ̀ pẹ.

17 Enia ti o ba hù ìwa-ika si ẹ̀jẹ ẹnikeji, yio sá lọ si ihò: ki ẹnikan ki o máṣe mu u.

18 Ẹnikẹni ti o ba nrin dẽde ni yio là: ṣugbọn ẹniti o nfi ayidayida rìn loju ọ̀na meji, yio ṣubu ninu ọkan ninu wọn.

19 Ẹniti o ba ro ilẹ rẹ̀ yio li ọ̀pọ onjẹ: ṣugbọn ẹniti o ba ntọ̀ enia asan lẹhin yio ni òṣi to.

20 Olõtọ enia yio pọ̀ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya.

21 Iṣojuṣãju enia kò dara: nitoripe fun òkele onjẹ kan, ọkunrin na yio ṣẹ̀.

22 Ẹniti o kanju ati là, o li oju ilara, kò si rò pe òṣi mbọ̀wá ta on.

23 Ẹniti o ba enia wi yio ri ojurere ni ikẹhin jù ẹniti nfi ahọn pọn ọ lọ.

24 Ẹnikẹni ti o ba nja baba tabi iya rẹ̀ li ole, ti o si wipe, kì iṣe ẹ̀ṣẹ; on na li ẹgbẹ apanirun.

25 Ẹniti o ṣe agberaga li aiya, a rú ìja soke, ṣugbọn ẹniti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o mu sanra.

26 Ẹniti o gbẹkẹ le aiya ara rẹ̀, aṣiwère ni; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nfi ọgbọ́n rìn, on li a o gbà la.

27 Ẹniti o ba nfi fun olupọnju kì yio ṣe alaini: ṣugbọn ẹniti o mu oju rẹ̀ kuro, yio gbà egún pupọ.

28 Nigbati enia buburu ba hù, awọn enia a sá pamọ́: ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣegbe, awọn olododo a ma pọ̀ si i.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31