Owe 17 YCE

1 OKELE gbigbẹ, ti on ti alafia, o san jù ile ti o kún fun ẹran-pipa ti on ti ìja.

2 Ọlọgbọ́n iranṣẹ yio ṣe olori ọmọ ti nhùwa itiju, yio si pin ogún lãrin awọn arakunrin.

3 Koro ni fun fadaka, ati ileru fun wura: bẹ̃li Oluwa ndan aiya wò.

4 Oluṣe buburu fetisi ète eke; ẹni-eké a si ma kiyesi ọ̀rọ ahọn buburu.

5 Ẹnikẹni ti o ba sín olupọnju jẹ, o gàn Ẹlẹda rẹ̀: ẹniti o ba si nyọ̀ si wahala kì yio wà li aijiya.

6 Ọmọ ọmọ li ade arugbo: ogo awọn ọmọ si ni baba wọn.

7 Ọ̀rọ daradara kò yẹ fun aṣiwère; bẹ̃li ète eke kò yẹ fun ọmọ-alade.

8 Okuta iyebiye jẹ ẹ̀bun li oju ẹniti o ni i; nibikibi ti o yi si, a ṣe rere.

9 Ẹniti o bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ, o nwá ifẹ; ṣugbọn ẹniti o tun ọ̀ran hú silẹ, o yà ọrẹ́ nipa.

10 Ibawi wọ̀ inu ọlọgbọ́n jù ọgọrun paṣan lọ ninu aṣiwère.

11 Ẹni-ọ̀tẹ a ma wá kiki ibi kiri; nitorina iranṣẹ ìka li a o ran si i.

12 O yá ki ẹranko beari ti a kó li ọmọ ki o pade enia, jù aṣiwère lọ ninu wère rẹ̀.

13 Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀.

14 Ẹniti o daju fun omi dabi olupilẹṣẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla.

15 Ẹniti o da enia buburu lare, ati ẹniti o da olododo lẹbi, ani awọn mejeji irira ni loju Oluwa.

16 Nitori kini iye owo yio ṣe wà lọwọ aṣiwère lati rà ọgbọ́n, sa wò o, kò ni oye?

17 Ọrẹ́ a ma fẹni nigbagbogbo, ṣugbọn arakunrin li a bi fun ìgba ipọnju.

18 Enia ti oye kù fun, a ṣe onigbọwọ, a si fi ara sọfà niwaju ọrẹ́ rẹ̀.

19 Ẹniti o fẹ ìja, o fẹ ẹ̀ṣẹ; ẹniti o kọ́ ẹnu-ọ̀na rẹ̀ ga, o nwá iparun.

20 Ẹniti o ni ayidayida ọkàn kì yio ri ire: ati ẹniti o ni ahọn ọ̀rọ-meji, a bọ sinu ibi.

21 Ẹniti o bi aṣiwère, o bi i si ibinujẹ rẹ̀; baba aṣiwère kò si li ayọ̀.

22 Inu-didùn mu imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mu egungun gbẹ.

23 Enia buburu mu ẹ̀bun lati iṣẹpo-aṣọ lati yi ọ̀na idajọ pada.

24 Ọgbọ́n wà niwaju ẹniti o moye; ṣugbọn oju aṣiwère mbẹ li opin ilẹ̀-aiye.

25 Aṣiwère ọmọ ni ibinujẹ baba rẹ̀, ati kikoro ọkàn fun iya ti o bi i.

26 Pẹlupẹlu kò dara ki a ṣẹ́ olotitọ ni iṣẹ́, tabi ki a lu ọmọ-alade nitori iṣedẽde.

27 Ẹniti o ni ìmọ, a ṣẹ́ ọ̀rọ rẹ̀ kù: ọlọkàn tutu si li amoye enia.

28 Lõtọ, aṣiwère, nigbati o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́, a kà a si ọlọgbọ́n; ẹniti o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si li amoye.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31