Owe 12 YCE

1 ẸNIKẸNI ti o fẹ ẹkọ́, o fẹ ìmọ: ṣugbọn ẹniti o korira ibawi, ẹranko ni.

2 Enia rere ni ojurere lọdọ Oluwa: ṣugbọn enia ete buburu ni yio dalẹbi.

3 A kì yio fi ẹsẹ enia mulẹ nipa ìwa-buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo kì yio fatu.

4 Obinrin oniwa-rere li ade ọkọ rẹ̀: ṣugbọn eyi ti ndojuti ni dabi ọyún ninu egungun rẹ̀.

5 Ìro olododo tọ́: ṣugbọn ìgbimọ awọn enia buburu, ẹ̀tan ni.

6 Ọ̀rọ enia buburu ni lati luba fun ẹ̀jẹ: ṣugbọn ẹnu aduro-ṣinsin ni yio gbà wọn silẹ.

7 A bì enia buburu ṣubu, nwọn kò si si: ṣugbọn ile olododo ni yio duro.

8 A o yìn enia gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ̀: ṣugbọn ẹni alayidayida aiya li a o gàn.

9 Ẹniti a ngàn, ti o si ni ọmọ-ọdọ, o san jù ẹ̀niti nyìn ara rẹ̀ ti kò si ni onjẹ.

10 Olododo enia mọ̀ ãjo ẹmi ẹran rẹ̀: ṣugbọn iyọ́nu awọn enia buburu, ìka ni.

11 Ẹniti o ro ilẹ rẹ̀ li a o fi onjẹ tẹlọrun: ṣugbọn ẹniti ntọ̀ enia-lasan lẹhin ni oye kù fun.

12 Enia buburu fẹ ilu-odi awọn enia buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo so eso.

13 Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju.

14 Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u.

15 Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n.

16 Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ.

17 Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan.

18 Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni.

19 Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni.

20 Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni.

21 Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi.

22 Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀.

23 Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere.

24 Ọwọ alãpọn ni yio ṣe akoso; ṣugbọn ọlẹ ni yio wà labẹ irú-sisìn.

25 Ibinujẹ li aiya enia ni idori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ rere ni imu u yọ̀.

26 Olododo tọ́ aladugbo rẹ̀ si ọ̀na; ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu tàn wọn jẹ.

27 Ọlẹ enia kò mu ohun ọdẹ rẹ̀; ṣugbọn lati jẹ alãpọn enia, ọrọ̀ iyebiye ni.

28 Li ọ̀na olododo ni ìye; ikú kò si loju ọ̀na otitọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31