5 Buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, bi ìṣina ti o ti ọdọ awọn ijoye wá.
6 A gbe aṣiwère sipò ọlá, awọn ọlọrọ̀ si joko nipò ẹhin.
7 Mo ri awọn ọmọ-ọdọ lori ẹṣin, ati awọn ọmọ-alade nrìn bi ọmọ-ọdọ ni ilẹ.
8 Ẹniti o wà iho ni yio bọ́ sinu rẹ̀; ati ẹniti o si njá ọgbà tútù, ejo yio si bù u ṣán.
9 Ẹnikan ti o nyi okuta ni yio si ti ipa rẹ̀ ni ipalara; ati ẹniti o si nla igi ni yio si wu li ewu.
10 Bi irin ba kújú, ti on kò si pọn oju rẹ̀, njẹ ki on ki o fi agbara si i; ṣugbọn ère ọgbọ́n ni lati fi ọ̀na hàn.
11 Nitõtọ bi ejo ba bu ni ṣán lainitùju; njẹ ère kì yio si fun onitùju.