2 Fi ipin fun meje ati fun mẹjọ pẹlu, nitoriti iwọ kò mọ̀ ibi ti yio wà laiye.
3 Bi awọsanma ba kún fun òjo, nwọn a si tu dà si aiye: bi igi ba si wó sìha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe.
4 Ẹniti o nkiyesi afẹfẹ kì yio funrugbin; ati ẹniti o si nwòju awọsanma kì yio ṣe ikore.
5 Bi iwọ kò ti mọ ipa-ọ̀na afẹfẹ, tabi bi egungun ti idàgba ninu aboyun: ani bẹ̃ni iwọ kò le mọ̀ iṣẹ Ọlọrun ti nṣe ohun gbogbo.
6 Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati li aṣãlẹ máṣe da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ̀ eyi ti yio ṣe rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna.
7 Nitõtọ imọlẹ dùn ati ohun didara ni fun oju lati wò õrùn.
8 Ṣugbọn bi enia wà li ọ̀pọlọpọ ọdun, ti o si nyọ̀ ninu gbogbo wọn, sibẹ, jẹ ki o ranti ọjọ òkunkun pe nwọn o pọ̀. Ohun gbogbo ti mbọ̀, asan ni.