1 RANTI ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ, nigbati ọjọ ibi kò ti ide, ati ti ọdun kò ti isunmọ etile, nigbati iwọ o wipe, emi kò ni inudidùn ninu wọn;
2 Nigbati õrùn, tabi imọlẹ, tabi oṣupa tabi awọn irawọ kò ti iṣu òkunkun, ati ti awọsanma kò ti itun pada lẹhin òjo:
3 Li ọjọ ti awọn oluṣọ ile yio warìri, ati ti awọn ọkunrin alagbara yio tẹri wọn ba, awọn õlọ̀ yio si dakẹ nitoriti nwọn kò to nkan, ati awọn ti nwode loju ferese yio ṣu òkunkun,
4 Ti ilẹkun yio si se ni igboro, nigbati iró ọlọ yio rẹlẹ, ti yio si dide li ohùn kike ẹiyẹ, ati ti gbogbo awọn ọmọbinrin orin yio rẹ̀ silẹ;
5 Ati pẹlu ti nwọn o bẹ̀ru ibi ti o ga, ti iwariri yio si wà li ọ̀na, ati ti igi almondi yio tanna, ti ẹlẹnga yio di ẹrù, ti ifẹ yio si ṣá: nitoriti ọkunrin nlọ si ile rẹ̀ pipẹ, awọn aṣọ̀fọ yio si ma yide kakiri.
6 Tabi ki okùn fadaka ki o to tu, tabi ki ọpọn wura ki o to fọ, tabi ki ìṣa ki o to fọ nibi isun, tabi ki ayika-kẹkẹ ki o to kán nibi kanga.