10 Oniwasu wadi ati ri ọ̀rọ didùn eyiti a si kọ, ohun iduro-ṣinṣin ni, ani ọ̀rọ otitọ.
11 Ọ̀rọ ọlọgbọ́n dabi ẹgún, ati awọn olori akojọ-ọ̀rọ bi iṣó ti a kàn, ti a nfi fun ni lati ọwọ oluṣọ-agutan kan wá.
12 Ati siwaju, lati inu eyi, ọmọ mi, ki o gbà ìmọran: ninu kikọ iwe pupọ, opin kò si: ati iwe kikà pupọ li ãrẹ̀ ara.
13 Opin gbogbo ọ̀rọ na ti a gbọ́ ni pe: Bẹ̀ru Ọlọrun ki o si pa ofin rẹ̀ mọ́: nitori eyi ni fun gbogbo enia.
14 Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.