5 Ati pẹlu ti nwọn o bẹ̀ru ibi ti o ga, ti iwariri yio si wà li ọ̀na, ati ti igi almondi yio tanna, ti ẹlẹnga yio di ẹrù, ti ifẹ yio si ṣá: nitoriti ọkunrin nlọ si ile rẹ̀ pipẹ, awọn aṣọ̀fọ yio si ma yide kakiri.
6 Tabi ki okùn fadaka ki o to tu, tabi ki ọpọn wura ki o to fọ, tabi ki ìṣa ki o to fọ nibi isun, tabi ki ayika-kẹkẹ ki o to kán nibi kanga.
7 Nigbana ni erupẹ yio pada si ilẹ bi o ti wà ri, ẹmi yio si pada tọ̀ Ọlọrun ti o fi i funni.
8 Asan ninu asan, oniwasu wipe, gbogbo rẹ̀ asan ni.
9 Ati pẹlu, nitori Oniwasu na gbọ́n, o si nkọ́ awọn enia ni ìmọ pẹlu; nitõtọ o ṣe akiyesi daradara, o si wadi, o si fi owe pupọ lelẹ li ẹsẹsẹ.
10 Oniwasu wadi ati ri ọ̀rọ didùn eyiti a si kọ, ohun iduro-ṣinṣin ni, ani ọ̀rọ otitọ.
11 Ọ̀rọ ọlọgbọ́n dabi ẹgún, ati awọn olori akojọ-ọ̀rọ bi iṣó ti a kàn, ti a nfi fun ni lati ọwọ oluṣọ-agutan kan wá.