14 Nitori ọrọ̀ wọnni a ṣegbe nipa iṣẹ buburu; bi o si bi ọmọkunrin kan, kò ni nkan lọwọ rẹ̀.
15 Bi o ti ti inu iya rẹ̀ jade wá, ihoho ni yio si tun pada lọ bi o ti wá, kì yio si mu nkan ninu lãla rẹ̀, ti iba mu lọ lọwọ rẹ̀.
16 Ibi buburu li eyi pẹlu, pe li ọ̀na gbogbo, bi o ti wá, bẹ̃ni yio si lọ: ère ki si ni fun ẹniti nṣe lãla fun afẹfẹ?
17 Li ọjọ rẹ̀ gbogbo pẹlu, o njẹun li òkunkun, o si ni ibinujẹ pupọ ati àrun ati irora rẹ̀.
18 Kiyesi eyi ti mo ri: o dara o si yẹ fun enia, ki o jẹ, ki o si mu, ki o si ma jẹ alafia ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn, ni iye ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, ti Ọlọrun fi fun u: nitori eyi ni ipin tirẹ̀.
19 Bi Ọlọrun ba fi ọrọ̀ fun ẹnikẹni, ti o si fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀: ati lati mu ipin rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu lãla rẹ eyi; pẹlu ẹ̀bun Ọlọrun ni.
20 Nitoriti kì yio ranti ọjọ aiye rẹ̀ pọju; nitoriti Ọlọrun da a lohùn ninu ayọ̀ ọkàn rẹ̀.