1 IBI kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, o si ṣọpọ lãrin awọn ọmọ enia.
2 Ẹniti Ọlọrun fi ọrọ̀, ọlà ati ọlá fun, ti kò si si nkan ti o si kù fun ọkàn rẹ̀ ninu ohun gbogbo ti o fẹ, ṣugbọn ti Ọlọrun kò fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn awọn ajeji enia li o njẹ ẹ: asan li eyi, àrun buburu si ni.
3 Bi ọkunrin kan bi ọgọrun ọmọ, ti o si wà li ọdun pupọ, tobẹ̃ ti ọjọ ọdun rẹ̀ pọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò si kún fun ohun didara, ati pẹlu ti a kò si sinkú rẹ̀; mo ni, ọmọ iṣẹnu san jù u lọ.
4 Nitoripe lasan li o wá, o si lọ li òkunkun, òkunkun li a o si fi bo orukọ rẹ̀ mọlẹ.