3 Bi ọkunrin kan bi ọgọrun ọmọ, ti o si wà li ọdun pupọ, tobẹ̃ ti ọjọ ọdun rẹ̀ pọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò si kún fun ohun didara, ati pẹlu ti a kò si sinkú rẹ̀; mo ni, ọmọ iṣẹnu san jù u lọ.
4 Nitoripe lasan li o wá, o si lọ li òkunkun, òkunkun li a o si fi bo orukọ rẹ̀ mọlẹ.
5 Pẹlupẹlu on kò ri õrùn kò mọ ohun kan: eyi ni isimi jù ekeji lọ.
6 Ani bi o tilẹ wà ni ẹgbẹrun ọdun lẹrin-meji, ṣugbọn kò ri rere: ibikanna ki gbogbo wọn ha nrè?
7 Gbogbo lãla enia ni fun ẹnu rẹ̀, ṣugbọn a kò ti itẹ adùn ọkàn rẹ̀ lọrun.
8 Nitoripe ère kili ọlọgbọ́n ni jù aṣiwère lọ? kini talaka ni ti o mọ̀ bi a ti rin niwaju awọn alãye?
9 Eyiti oju ri san jù irokakiri ifẹ lọ; asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.