8 Kò si enia kan ti o lagbara lori ẹmi lati da ẹmi duro; bẹ̃ni kò si lagbara li ọjọ ikú: kò si iránpada ninu ogun na; bẹ̃ni ìwa buburu kò le gbà awọn oluwa rẹ̀.
9 Gbogbo nkan wọnyi ni mo ri, mo si fiyè si iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn: ìgba kan mbẹ ninu eyi ti ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.
10 Bẹ̃ni mo si ri isinkú enia buburu, ati awọn ti o ṣe otitọ ti o wá ti o si lọ kuro ni ibi mimọ́, a si gbagbe wọn ni ilu na: asan li eyi pẹlu.
11 Nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pãpa lati huwa ibi.
12 Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rẹ̀ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ̀ pe yio dara fun awọn ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o bẹ̀ru niwaju rẹ̀:
13 Ṣugbọn kì yio dara fun enia buburu, bẹ̃ni kì yio fa ọjọ rẹ̀ gun ti o dabi ojiji, nitoriti kò bẹ̀ru niwaju Ọlọrun.
14 Asan kan mbẹ ti a nṣe li aiye; niti pe, olõtọ enia wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ buburu; ati pẹlu, enia buburu wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ olododo: mo ni asan li eyi pẹlu.