12 Nitoripe enia pẹlu kò mọ̀ ìgba tirẹ̀; bi ẹja ti a mu ninu àwọn buburu, ati bi ẹiyẹ ti a mu ninu okùn; bẹ̃li a ndẹ awọn ọmọ enia ni ìgba buburu, nigbati o ṣubu lù wọn lojiji.
13 Ọgbọ́n yi ni mo ri pẹlu labẹ õrùn, o si dabi ẹnipe o tobi fun mi.
14 Ilu kekere kan wà, ati enia diẹ ninu rẹ̀; ọba nla kan si ṣigun tọ̀ ọ lọ, o si dótì i, o si mọ ile-iṣọ ti o tobi tì i.
15 A si ri ọkunrin talaka ọlọgbọ́n ninu rẹ̀, on si fi ọgbọ́n rẹ̀ gbà ilu na silẹ; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o ranti ọkunrin talaka na.
16 Nigbana ni mo wipe, Ọgbọ́n san jù agbara lọ; ṣugbọn a kẹgan ọgbọ́n ọkunrin talaka na, ohùn rẹ̀ kò si to òke.
17 A ngbọ́ ọ̀rọ ọlọgbọ́n enia ni pẹlẹ jù igbe ẹniti njẹ olori ninu awọn aṣiwère.
18 Ọgbọ́n san jù ohun-elo ogun: ṣugbọn ẹ̀lẹṣẹ kan o ba ohun didara pupọ jẹ.