1 NITORI emi kò fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀, ara, bi gbogbo awọn baba wa ti wà labẹ awọsanma, ti gbogbo wọn si là okun já;
2 Ti a si baptisi gbogbo wọn si Mose ninu awọsanma ati ninu okun;
3 Ti gbogbo wọn si ti jẹ onjẹ ẹmí kanna;
4 Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na.