3 Ti gbogbo wọn si ti jẹ onjẹ ẹmí kanna;
4 Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na.
5 Ṣugbọn ọ̀pọlọpọ wọn ni inu Ọlọrun kò dùn si: nitoripe a bì wọn ṣubu li aginjù.
6 Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ.
7 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire.
8 Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan.
9 Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn.