4 Olukuluku ọkunrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ ti o bo ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀.
5 Ṣugbọn olukuluku obinrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ li aibò ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀: nitori ọkanna ni pẹlu ẹniti o fári.
6 Nitori bi obinrin kò ba bo ori, ẹ jẹ ki o rẹ́ irun rẹ̀ pẹlu: ṣugbọn bi o bá ṣepe ohun itiju ni fun obinrin lati rẹ́ irun tabi lati fári rẹ̀, jẹ ki o bò ori.
7 Nitori nitõtọ kò yẹ ki ọkunrin ki o bò ori rẹ̀, niwọnbi on ti jẹ aworan ati ogo Ọlọrun: ṣugbọn obinrin ni iṣe ogo ọkunrin.
8 Nitori ọkunrin kò ti ara obinrin wá; ṣugbọn obinrin ni o ti ara ọkunrin wá.
9 Bẹ̃ni a kò dá ọkunrin nitori obinrin; ṣugbọn a da obinrin nitori ọkunrin.
10 Nitori eyi li o fi yẹ fun obinrin lati ni ami aṣẹ li ori rẹ̀, nitori awọn angẹli.