7 Ṣugbọn kọ̀ ọrọ asan ati itan awọn agba obinrin, si mã tọ́ ara rẹ si ìwa-bi-Ọlọrun.
8 Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀.
9 Otitọ ni ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà gbogbo.
10 Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́.
11 Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni.
12 Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́.
13 Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni.