Ifi 10 YCE

Angẹli ati Ìwé-kíká Kékeré

1 MO si ri angẹli miran alagbara o nti ọrun sọkalẹ wá, a fi awọsanma wọ̀ ọ li aṣọ: oṣumare si mbẹ li ori rẹ̀, oju rẹ̀ si dabi õrùn, ati ẹsẹ rẹ̀ bi ọwọ̀n iná:

2 O si ni iwe kekere kàn ti a ṣi li ọwọ́ rẹ̀: o si fi ẹsẹ rẹ̀ ọtun le okun, ati ẹsẹ rẹ̀ òsi le ilẹ,

3 O si ke li ohùn rara, bi igbati kiniun ba bú ramuramu: nigbati o si ké, awọn ãrá meje na fọhun.

4 Nigbati awọn ãrá meje na fọhun, mo mura ati kọwe: mo si gbọ́ ohùn lati ọrun wá nwi fun mi pe, Fi èdidi dí ohun ti awọn ãrá meje na sọ, má si ṣe kọ wọn silẹ.

5 Angẹli na ti mo ri ti o duro lori okun ati lori ilẹ, si gbé ọwọ́ rẹ̀ si oke ọrun,

6 O si fi ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai búra, ẹniti o dá ọrun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ aiye, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati okun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, pe ìgba kì yio si mọ́:

7 Ṣugbọn li ọjọ ohùn angẹli keje, nigbati yio ba fun ipe, nigbana li ohun ijinlẹ Ọlọrun pari, gẹgẹ bi ihinrere ti o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli.

8 Ohùn na ti mo gbọ́ lati ọrun wá tún mba mi sọrọ, o si wipe, Lọ, gbà iwe ti o ṣí nì lọwọ angẹli ti o duro lori okun ati lori ilẹ.

9 Mo si tọ̀ angẹli na lọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni iwe kekere nì. O si wi fun mi pe, Gbà ki o si jẹ ẹ tan; yio mu inu rẹ korò, ṣugbọn li ẹnu rẹ yio dabi oyin.

10 Mo si gbà iwe kekere na li ọwọ́ angẹli na, mo si jẹ ẹ tan; o si dùn li ẹnu mi bi oyin: bi mo si ti jẹ ẹ tan, inu mi korò.

11 A si wi fun mi pe, Iwọ o tún sọ asọtẹlẹ lori ọpọlọpọ enia, ati orilẹ, ati ède, ati awọn ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22