Ifi 20 YCE

Ìjọba Ẹgbẹrun Ọdún

1 MO si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wá, ti on ti ìṣika ọgbun nì, ati ẹ̀wọn nla kan li ọwọ́ rẹ̀.

2 O si di dragoni na mu, ejò atijọ nì, ti iṣe Èṣu, ati Satani, o si dè e li ẹgbẹ̀run ọdún.

3 O si gbé e sọ sinu ọgbun na, o si ti i, o si fi èdidi di i lori rẹ̀, ki o má bã tan awọn orilẹ-ède jẹ mọ́ titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé: lẹhin eyi, a kò le ṣai tu u silẹ fun igba diẹ.

4 Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún.

5 Awọn okú iyokù kò wà lãye mọ́ titi ẹgbẹ̀run ọdún na yio fi pé. Eyi li ajinde ekini.

6 Olubukun ati mimọ́ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mã jọba pẹlu rẹ̀ li ẹgbẹ̀run ọdún.

A Ṣẹgun Satani

7 Nigbati ẹgbẹrun ọdún na ba si pé, a o tú Satani silẹ kuro ninu tubu rẹ̀.

8 Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun.

9 Nwọn si gòke lọ la ibú aiye ja, nwọn si yi ibudo awọn enia mimọ́ ká ati ilu ayanfẹ na: iná si ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo wọn run.

10 A si wọ́ Èṣu ti o tàn wọn jẹ lọ sinu adagun iná ati sulfuru, nibiti ẹranko ati woli eke nì gbé wà, a o si mã dá wọn loro t'ọsan-t'oru lai ati lailai.

Ìdájọ́ Ìkẹyìn

11 Mo si ri itẹ́ funfun nla kan, ati ẹni ti o joko lori rẹ̀, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri ãye fun wọn mọ́.

12 Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

13 Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

14 Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná. Eyi ni ikú keji.

15 Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22