Ifi 16 YCE

Àwọn Àwo tí Ó Kún fún Ibinu Ọlọrun

1 MO si gbọ́ ohùn nla kan lati inu tẹmpili wá, nwi fun awọn angẹli meje nì pe, Ẹ lọ, ẹ si tú ìgo ibinu Ọlọrun wọnni si ori ilẹ aiye.

2 Ekini si lọ, o si tú ìgo tirẹ̀ si ori ilẹ aiye; egbò kikẹ̀ ti o si dibajẹ si dá awọn enia ti o ni àmi ẹranko na, ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀.

3 Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun.

4 Ẹkẹta si tú ìgo tirẹ̀ sinu odò, ati si orisun awọn omi; nwọn si di ẹ̀jẹ.

5 Mo si gbọ́ angẹli ti omi nì wipe, Olododo ni Iwọ Ẹni-Mimọ́, ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, nitoriti iwọ ṣe idajọ bayi.

6 Nitoriti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́ ati ti awọn woli silẹ, iwọ si fi ẹ̀jẹ fun wọn mu; eyiyi li o yẹ wọn.

7 Mo si gbọ́ pẹpẹ nke wipe, Bẹ̃ni, Oluwa Ọlọrun Olodumare, otitọ ati ododo ni idajọ rẹ.

8 Ẹkẹrin si tú ìgo tirẹ̀ sori õrùn; a si yọnda fun u lati fi iná jó enia lara.

9 A si fi õru nla jo awọn enia lara, nwọn si sọ̀rọ-òdi si orukọ Ọlọrun, ẹniti o li agbara lori iyọnu wọnyi: nwọn kò si ronupiwada lati fi ogo fun u.

10 Ẹkarun si tu ìgo tirẹ̀ sori ìtẹ ẹranko na; ilẹ-ọba rẹ̀ si ṣokunkun; nwọn si nge ahọn wọn jẹ nitori irora.

11 Nwọn si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ọrun nitori irora wọn ati nitori egbò wọn, nwọn kò si ronupiwada iṣẹ wọn.

12 Ẹkẹfa si tú ìgo tirẹ̀ sori odò nla Eufrate; omi rẹ̀ si gbẹ, ki a le pese ọna fun awọn ọba ati ìla-õrùn wá.

13 Mo si ri awọn ẹmí aimọ́ mẹta bi ọ̀pọlọ́, nwọn ti ẹnu dragoni na ati ẹnu ẹranko na ati ẹnu woli eke na jade wá.

14 Nitori ẹmi èṣu ni wọn, ti nṣe iṣẹ-iyanu, awọn ti njade lọ sọdọ awọn ọba gbogbo ilẹ aiye, lati gbá wọn jọ si ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.

15 Kiyesi i, mo mbọ̀ bi olè. Ibukún ni fun ẹniti nṣọna, ti o si npa aṣọ rẹ̀ mọ́, ki o má bã rìn ni ìhoho, nwọn a si ri itiju rẹ̀.

16 O si gbá wọn jọ si ibikan ti a npè ni Har-mageddoni li ède Heberu.

17 Ekeje si tú ìgo tirẹ̀ si oju ọrun; ohùn nla kan si ti inu tẹmpili jade lati ibi itẹ́, wipe, O pari.

18 Mànamána si kọ, a si gbọ́ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, iru eyiti kò ṣẹ̀ ri lati igbati enia ti wà lori ilẹ, iru ìṣẹlẹ nla bẹ̃, ti o si lagbara tobẹ̃.

19 Ilu nla na si pin si ipa mẹta, awọn orilẹ-ède si ṣubu: Babiloni nla si wá si iranti niwaju Ọlọrun, lati fi ãgo ọti-waini ti irunu ibinu rẹ̀ fun u.

20 Olukuluku erekuṣu si salọ, a kò si ri awọn òke nla mọ́.

21 Yinyín nla, ti ọkọ̃kan rẹ̀ to talenti ni ìwọ̀n, si bọ́ lù awọn enia lati ọrun wà: awọn enia si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun nitori iyọnu yinyín na; nitoriti iyọnu rẹ̀ na pọ̀ gidigidi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22