Ifi 4 YCE

Ìsìn ní Ọ̀run

1 LẸHIN nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan ṣí silẹ li ọrun: ohùn kini ti mo gbọ bi ohùn ipè ti mba mi sọ̀rọ, ti o wipe, Goke wa ìhin, emi o si fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn ọ.

2 Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na.

3 Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo.

4 Yi itẹ́ na ká si ni itẹ́ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ́ na mo ri awọn àgba mẹrinlelogun joko, ti a wọ̀ li aṣọ àlà; ade wura si wà li ori wọn.

5 Ati lati ibi itẹ́ na ni mànamána ati ãrá ati ohùn ti jade wá: fitila iná meje si ntàn nibẹ̀ niwaju itẹ́ na, ti iṣe Ẹmi meje ti Ọlọrun.

6 Ati niwaju itẹ́ na si ni okun bi digí, o dabi kristali: li arin itẹ́ na, ati yi itẹ́ na ká, li ẹda alãye mẹrin ti o kún fun oju niwaju ati lẹhin.

7 Ẹda ikini si dabi kiniun, ẹda keji si dabi ọmọ malu, ẹda kẹta si ni oju bi ti enia, ẹda kẹrin si dabi idì ti nfò.

8 Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ́ mẹfa, kun fun oju yika ati ninu: nwọn kò si simi li ọsán ati li oru, wipe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, Oluwa Ọlọrun Olodumare, ti o ti wà, ti o si mbẹ, ti o si mbọ̀wá.

9 Nigbati awọn ẹda alãye na ba si fi ogo ati ọlá ati ọpẹ́ fun ẹniti o joko lori itẹ́, ti o mbẹ lãye lai ati lailai,

10 Awọn àgba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹniti o joko lori itẹ́, nwọn a si tẹriba fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai, nwọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ́ na, wipe,

11 Oluwa, iwọ li o yẹ lati gbà ogo ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni nwọn fi wà ti a si dá wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22