11 Ati lẹhin ijọ mẹta on àbọ na, ẹmí ìye lati ọdọ Ọlọrun wá wọ̀ inu wọn, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn; ẹ̀ru nla si ba awọn ti o ri wọn.
12 Nwọn si gbọ́ ohùn nla kan lati ọrun wá nwi fun wọn pe, Ẹ gòke wá ìhin. Nwọn si gòke lọ si ọrun ninu awọsanma; awọn ọtá wọn si ri wọn.
13 Ni wakati na ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀, idamẹwa ilu na si wó, ati ninu ìṣẹlẹ na ẹdẹgbarin enia li a pa: ẹ̀ru si ba awọn iyokù, nwọn si fi ogo fun Ọlọrun ọrun.
14 Egbé keji kọja; si kiyesi i, egbé kẹta si mbọ̀wá kánkán.
15 Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai.
16 Awọn àgba mẹrinlelogun nì ti nwọn joko niwaju Ọlọrun lori ítẹ wọn, dojubolẹ, nwọn si sìn Ọlọrun,
17 Wipe, Awa fi ọpẹ́ fun ọ, Oluwa Ọlọrun, Olodumare, ti mbẹ, ti o si ti wà, ti o si ma bọ̀; nitoriti iwọ ti gbà agbara nla rẹ, iwọ si ti jọba.