5 Bi ẹnikẹni ba si fẹ pa wọn lara, iná a ti ẹnu wọn jade, a si pa awọn ọtá wọn run: bi ẹnikẹni yio ba si fẹ pa wọn lara, bayi li o yẹ ki a pa a.
6 Awọn wọnyi li o ni agbara lati sé ọrun, ti ojo kò fi rọ̀ li ọjọ asọtẹlẹ wọn: nwọn si ni agbara lori omi lati sọ wọn di ẹ̀jẹ, ati lati fi oniruru ajakalẹ arun kọlu aiye, nigbakugba ti nwọn ba fẹ.
7 Nigbati nwọn ba si ti pari ẹrí wọn, ẹranko ti o nti inu ọ̀gbun goke wá ni yio ba wọn jagun, yio si ṣẹgun wọn, yio si pa wọn.
8 Okú wọn yio si wà ni igboro ilu nla nì, ti a npè ni Sodomu ati Egipti nipa ti ẹmí, nibiti a gbé kàn Oluwa wọn mọ agbelebu.
9 Ati ninu awọn enia, ati ẹya, ati ède, ati orilẹ, nwọn wo okú wọn fun ijọ mẹta on àbọ, nwọn kò si jẹ ki a gbé okú wọn sinu isà okú.
10 Ati awọn ti o ngbé ori ilẹ aiye yio si yọ̀ le wọn lori, nwọn si ṣe ariya, nwọn o si ta ara wọn lọrẹ; nitoriti awọn woli mejeji yi dá awọn ti o mbẹ lori ilẹ aiye loró.
11 Ati lẹhin ijọ mẹta on àbọ na, ẹmí ìye lati ọdọ Ọlọrun wá wọ̀ inu wọn, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn; ẹ̀ru nla si ba awọn ti o ri wọn.