9 Ati ninu awọn enia, ati ẹya, ati ède, ati orilẹ, nwọn wo okú wọn fun ijọ mẹta on àbọ, nwọn kò si jẹ ki a gbé okú wọn sinu isà okú.
10 Ati awọn ti o ngbé ori ilẹ aiye yio si yọ̀ le wọn lori, nwọn si ṣe ariya, nwọn o si ta ara wọn lọrẹ; nitoriti awọn woli mejeji yi dá awọn ti o mbẹ lori ilẹ aiye loró.
11 Ati lẹhin ijọ mẹta on àbọ na, ẹmí ìye lati ọdọ Ọlọrun wá wọ̀ inu wọn, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn; ẹ̀ru nla si ba awọn ti o ri wọn.
12 Nwọn si gbọ́ ohùn nla kan lati ọrun wá nwi fun wọn pe, Ẹ gòke wá ìhin. Nwọn si gòke lọ si ọrun ninu awọsanma; awọn ọtá wọn si ri wọn.
13 Ni wakati na ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀, idamẹwa ilu na si wó, ati ninu ìṣẹlẹ na ẹdẹgbarin enia li a pa: ẹ̀ru si ba awọn iyokù, nwọn si fi ogo fun Ọlọrun ọrun.
14 Egbé keji kọja; si kiyesi i, egbé kẹta si mbọ̀wá kánkán.
15 Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai.