12 O si nlò gbogbo agbara ẹranko ekini niwaju rẹ̀, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ foribalẹ fun ẹranko ekini ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ̀ san.
13 O si nṣe ohun iyanu nla, ani ti o fi nmu iná sọkalẹ lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia.
14 O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè.
15 A si fi fun u lati fi ẹmí fun aworan ẹranko na ki o mã sọ̀rọ, ki o si mu ki a pa gbogbo awọn ti kò foribalẹ fun aworan ẹranko na.
16 O si mu gbogbo wọn, ati kekere ati nla, ọlọrọ̀ ati talakà, omnira ati ẹrú, ki a fi àmi kan fun wọn li ọwọ́ ọtún wọn, tabi ni iwaju wọn:
17 Ati ki ẹnikẹni má le rà tabi ki o tà, bikoṣe ẹniti o bá ni ami orukọ ẹranko na, tabi iye orukọ rẹ̀.
18 Nihin ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹniti o ba ni oye, ki o ṣiro iye ti mbẹ lara ẹranko na: nitori iye enia ni; iye rẹ̀ na si jẹ ọ̀talelẹgbẹta o le mẹfa.